Hosea 11:10
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọn yóò máa tẹ̀lé Olúwa; òun yóò bú ramúramù bí i kìnnìún. Nígbà tó bá bú, àwọn ọmọ rẹ yóò wá ní ìwárìrì láti ìwọ̀-oòrùn.
Hosea 11:10 in English
Hosea 11:10 · Berean Standard Bible
They will walk after the LORD; He will roar like a lion. When He roars, His children will come trembling from the west.
Context
8“Báwo ni èmi ó ṣe fi ọ́ sílẹ̀, Efraimu?
Báwo ni èmi ó ṣe yọ̀ǹda rẹ̀, Israẹli?
Báwo ni mo ṣe lè ṣe ọ bi i Adma?
Báwo ni mo ṣe lè ṣe ọ bi i Seboimu?
Ọkàn mi yípadà nínú mi
àánú mi sì ru sókè. 9Èmi kò ni mú ìbínú gbígbóná mi ṣẹ,
tàbí kí èmi wá sọ Efraimu di ahoro.
Nítorí pé èmi ni Ọlọ́run, àní, èmi kì í ṣe ènìyàn.
Ẹni mímọ́ láàrín yín,
Èmi kò ní í wá nínú ìbínú. 10Wọn yóò máa tẹ̀lé Olúwa;
òun yóò bú ramúramù bí i kìnnìún.
Nígbà tó bá bú,
àwọn ọmọ rẹ yóò wá ní ìwárìrì láti ìwọ̀-oòrùn. 11Wọn ó wá pẹ̀lú ẹ̀rù
bí i ẹyẹ láti Ejibiti,
bí i àdàbà láti Asiria,
Èmi ó mú wọn padà sí ilé wọn,”
ni Olúwa wí. 12Efraimu tí fi irọ́ yí mi ká
ilé Israẹli pẹ̀lú ẹ̀tàn.
Ṣùgbọ́n Juda sì dúró ṣinṣin pẹ̀lú Ọlọ́run.
Ó sì ṣe olóòtítọ́ sí Ẹni mímọ́ Israẹli.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.