Native Bible

Hebrews 5:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí ó ti wí pẹ̀lú ní ibòmíràn pé, “Ìwọ ni àlùfáà títí láé ní ipasẹ̀ Melkisedeki.”

Hebrews 5:6 in English

Hebrews 5:6 · Berean Standard Bible

And in another passage God says: “You are a priest forever in the order of Melchizedek.”*

Context

4Kọ sí ẹni tí o gba ọlá yìí fún ara rẹ̀, bí kò ṣe ẹni tí a pè láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá gẹ́gẹ́ bí a ti pe Aaroni. 5Bẹ́ẹ̀ ni Kristi pẹ̀lú kò sì ṣe ara rẹ̀ lógo láti jẹ́ olórí àlùfáà; bí kò ṣe ẹni tí o wí fún ún pé, “Ìwọ ni ọmọ mi, lónìí ni mo bí ọ.” 6Bí ó ti wí pẹ̀lú ní ibòmíràn pé, “Ìwọ ni àlùfáà títí láé ní ipasẹ̀ Melkisedeki.” 7Ní ìgbà ọjọ́ Jesu nínú ayé, ó fi ìkérora rara àti omijé gbàdúrà, tí ó sì bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ ẹni tí ó lè gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú, a sì gbóhùn rẹ̀ nítorí ó ní ẹ̀mí ìbẹ̀rù Ọlọ́run rẹ̀. 8Bí òun tilẹ̀ ń ṣe Ọmọ Ọlọ́run, síbẹ̀ ó kọ́ ìgbọ́ran nípa ohun tí ó jìyà rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.