Heberu 4:5
Hebrews 4:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àti níhìn-ín yìí pẹ̀lú ó wí pé, “Wọn kì yóò wọ inú ìsinmi mi.”
Hebrews 4:5 in English
Hebrews 4:5 · Berean Standard Bible
And again, as He says in the passage above: “They shall never enter My rest.”
Context
3Nítorí pé àwa tí ó ti gbàgbọ́ wọ inú ìsinmi gẹ́gẹ́ bí ó tí wí,
“Bí mo tí búra nínú ìbínú mi,
‘Wọn kì yóò wọ inú ìsinmi mi.’ ”
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a tí parí iṣẹ́ wọ̀nyí láti ìpìlẹ̀ ayé. 4Nítorí ó ti sọ níbìkan ní ti ọjọ́ keje báyìí pé, “Ọlọ́run sì sinmi ní ọjọ́ keje kúrò nínú iṣẹ́ rẹ̀ gbogbo.” 5Àti níhìn-ín yìí pẹ̀lú ó wí pé, “Wọn kì yóò wọ inú ìsinmi mi.” 6Nítorí náà bí ó tí jẹ́ pé, ó ku kí àwọn kan wọ inú rẹ̀, àti àwọn tí a ti wàásù ìyìnrere náà fún ní ìṣáájú kò wọ inú rẹ̀ nítorí àìgbọ́ràn. 7Àti pé, ó yan ọjọ́ kan, ó wí nínú ìwé Dafidi pé, “Lónìí,” lẹ́yìn ìgbà pípẹ́ bẹ́ẹ̀; bí a tí wí níṣàájú,
“Lónìí bí ẹ̀yin bá gbọ́ ohùn rẹ̀,
ẹ má ṣe sé ọkàn yín le.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.