Native Bible

Hebrews 4:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí pé àwa tí ó ti gbàgbọ́ wọ inú ìsinmi gẹ́gẹ́ bí ó tí wí, “Bí mo tí búra nínú ìbínú mi, ‘Wọn kì yóò wọ inú ìsinmi mi.’ ” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a tí parí iṣẹ́ wọ̀nyí láti ìpìlẹ̀ ayé.

Hebrews 4:3 in English

Hebrews 4:3 · Berean Standard Bible

Now we who have believed enter that rest. As for the others, it is just as God has said: “So I swore on oath in My anger, ‘They shall never enter My rest.’”* And yet His works have been finished since the foundation of the world.

Context

1Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti ṣe ìlérí àtiwọ inú ìsinmi rẹ̀ fún wa, ẹ jẹ́ kí á bẹ̀rù, kí ẹnikẹ́ni nínú yín má ba à dàbí ẹni pé ó tí kùnà rẹ̀. 2Nítorí tí àwa gbọ́ ìwàásù ìyìnrere, gẹ́gẹ́ bí a ti wàásù rẹ̀ fún àwọn náà pẹ̀lú, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ tí wọ́n gbọ́ kò ṣe wọ́n ní àǹfààní, nítorí tí kò dàpọ̀ mọ́ ìgbàgbọ́ nínú àwọn tí ó gbọ́ ọ. 3Nítorí pé àwa tí ó ti gbàgbọ́ wọ inú ìsinmi gẹ́gẹ́ bí ó tí wí, “Bí mo tí búra nínú ìbínú mi, ‘Wọn kì yóò wọ inú ìsinmi mi.’ ” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a tí parí iṣẹ́ wọ̀nyí láti ìpìlẹ̀ ayé. 4Nítorí ó ti sọ níbìkan ní ti ọjọ́ keje báyìí pé, “Ọlọ́run sì sinmi ní ọjọ́ keje kúrò nínú iṣẹ́ rẹ̀ gbogbo.” 5Àti níhìn-ín yìí pẹ̀lú ó wí pé, “Wọn kì yóò wọ inú ìsinmi mi.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.