Heberu 4:7
Hebrews 4:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àti pé, ó yan ọjọ́ kan, ó wí nínú ìwé Dafidi pé, “Lónìí,” lẹ́yìn ìgbà pípẹ́ bẹ́ẹ̀; bí a tí wí níṣàájú, “Lónìí bí ẹ̀yin bá gbọ́ ohùn rẹ̀, ẹ má ṣe sé ọkàn yín le.”
Hebrews 4:7 in English
Hebrews 4:7 · Berean Standard Bible
God again designated a certain day as “Today,” when a long time later He spoke through David as was just stated: “Today, if you hear His voice, do not harden your hearts.”*
Context
5Àti níhìn-ín yìí pẹ̀lú ó wí pé, “Wọn kì yóò wọ inú ìsinmi mi.” 6Nítorí náà bí ó tí jẹ́ pé, ó ku kí àwọn kan wọ inú rẹ̀, àti àwọn tí a ti wàásù ìyìnrere náà fún ní ìṣáájú kò wọ inú rẹ̀ nítorí àìgbọ́ràn. 7Àti pé, ó yan ọjọ́ kan, ó wí nínú ìwé Dafidi pé, “Lónìí,” lẹ́yìn ìgbà pípẹ́ bẹ́ẹ̀; bí a tí wí níṣàájú,
“Lónìí bí ẹ̀yin bá gbọ́ ohùn rẹ̀,
ẹ má ṣe sé ọkàn yín le.” 8Nítorí, ìbá ṣe pé Joṣua tí fún wọn ní ìsinmi, òun kì bá tí sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ ìsinmi mìíràn lẹ́yìn náà, 9nítorí náà ìsinmi kan kù fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.