Native Bible

Hebrews 2:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n ibìkan wà tí ẹnìkan tí jẹ́rìí pé “Kí ni ènìyàn tí ìwọ fi ń ṣe ìrántí rẹ̀, tàbí ọmọ ènìyàn, tí ìwọ fi ń bẹ̀ ẹ́ wò?

Hebrews 2:6 in English

Hebrews 2:6 · Berean Standard Bible

But somewhere it is testified in these words: “What is man that You are mindful of him, or the son of man that You care for him?

Context

4Ọlọ́run jẹ́rìí sí i nípa àwọn iṣẹ́ àmì àti ìyanu àti oríṣìíríṣìí iṣẹ́ agbára àti nípa ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ tí a pín gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀. 5Nítorí pé, kì í ṣe abẹ́ ìṣàkóso àwọn angẹli ni ó fi ayé tí ń bọ̀, tí àwa ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ sí. 6Ṣùgbọ́n ibìkan wà tí ẹnìkan tí jẹ́rìí pé “Kí ni ènìyàn tí ìwọ fi ń ṣe ìrántí rẹ̀, tàbí ọmọ ènìyàn, tí ìwọ fi ń bẹ̀ ẹ́ wò? 7Ìwọ dá a ní onírẹ̀lẹ̀ díẹ̀ ju àwọn angẹli lọ; ìwọ fi ògo àti ọlá de e ni adé, ìwọ sì fi í jẹ olórí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ, 8Ìwọ fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.” Ní ti fífi ohun gbogbo sábẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n àwa kò ì tí ì rí ohun kan tí ó kù tí kò sí ní abẹ́ àkóso rẹ̀. Síbẹ̀ nísinsin yìí àwa kò ì tí ì rí pé ó fi ohun gbogbo sábẹ́ ìṣàkóso rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.