Heberu 2:8
Hebrews 2:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìwọ fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.” Ní ti fífi ohun gbogbo sábẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n àwa kò ì tí ì rí ohun kan tí ó kù tí kò sí ní abẹ́ àkóso rẹ̀. Síbẹ̀ nísinsin yìí àwa kò ì tí ì rí pé ó fi ohun gbogbo sábẹ́ ìṣàkóso rẹ̀.
Hebrews 2:8 in English
Hebrews 2:8 · Berean Standard Bible
and placed everything under his feet.”* When God subjected all things to him, He left nothing outside of his control. Yet at present we do not see everything subject to him.
Context
6Ṣùgbọ́n ibìkan wà tí ẹnìkan tí jẹ́rìí pé
“Kí ni ènìyàn tí ìwọ fi ń ṣe ìrántí rẹ̀,
tàbí ọmọ ènìyàn, tí ìwọ fi ń bẹ̀ ẹ́ wò? 7Ìwọ dá a ní onírẹ̀lẹ̀ díẹ̀ ju àwọn angẹli lọ;
ìwọ fi ògo àti ọlá de e ni adé,
ìwọ sì fi í jẹ olórí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ, 8Ìwọ fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.”
Ní ti fífi ohun gbogbo sábẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n àwa kò ì tí ì rí ohun kan tí ó kù tí kò sí ní abẹ́ àkóso rẹ̀. Síbẹ̀ nísinsin yìí àwa kò ì tí ì rí pé ó fi ohun gbogbo sábẹ́ ìṣàkóso rẹ̀. 9Ṣùgbọ́n àwa rí Jesu ẹni tí a rẹ̀ sílẹ̀ díẹ̀ ju àwọn angẹli lọ fún àkókò díẹ̀, àní Jesu, ẹni tí a fi ògo àti ọlá dé ní adé nítorí ìjìyà wa; kí ó lè tọ́ ikú wò fún olúkúlùkù ènìyàn nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run. 10Nítorí pé ó yẹ fún Ọlọ́run, nítorí nípasẹ̀ ẹni tí ohun gbogbo ṣẹ̀ wà, láti mú àwọn ọmọ púpọ̀ wá sínú ògo, láti ṣe balógun ìgbàlà wọn ni àṣepé nípa ìjìyà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.