Native Bible

Hebrews 13:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kí ọkàn yín má ṣe fà sí ìfẹ́ owó, ki ohun tí ẹ ní tó yin; nítorí òun tìkára rẹ̀ ti wí pé, “Èmi kò jẹ́ fi ọ́ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò jẹ́ kọ̀ ọ́ sílẹ̀.”

Hebrews 13:5 in English

Hebrews 13:5 · Berean Standard Bible

Keep your lives free from the love of money and be content with what you have, for God has said: “Never will I leave you, never will I forsake you.”*

Context

3Ẹ máa rántí àwọn òǹdè bí ẹni tí a dè pẹ̀lú wọn, àti àwọn tí a ń pọn lójú bí ẹ̀yin tìkára yín pẹ̀lú tí ń bẹ nínú ara. 4Kí ìgbéyàwó lọ́lá láàrín gbogbo ènìyàn, kí àkéte si jẹ́ aláìléèérí, nítorí àwọn àgbèrè àti àwọn panṣágà ni Ọlọ́run yóò dá lẹ́jọ́. 5Kí ọkàn yín má ṣe fà sí ìfẹ́ owó, ki ohun tí ẹ ní tó yin; nítorí òun tìkára rẹ̀ ti wí pé, “Èmi kò jẹ́ fi ọ́ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò jẹ́ kọ̀ ọ́ sílẹ̀.” 6Nítorí náà ni àwa ṣe ń fi ìgboyà wí pé, “Olúwa ni olùrànlọ́wọ́ mi, èmi kì yóò bẹ̀rù; kín ni ènìyàn lè ṣe sí mi?” 7Ẹ máa rántí àwọn tiwọn jẹ́ aṣáájú yín, tiwọn ti sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún yín; kí ẹ máa ro òpin ìwà ayé wọn, kí ẹ sì máa ṣe àfarawé ìgbàgbọ́ wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.