Heberu 13:4
Hebrews 13:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kí ìgbéyàwó lọ́lá láàrín gbogbo ènìyàn, kí àkéte si jẹ́ aláìléèérí, nítorí àwọn àgbèrè àti àwọn panṣágà ni Ọlọ́run yóò dá lẹ́jọ́.
Hebrews 13:4 in English
Hebrews 13:4 · Berean Standard Bible
Marriage should be honored by all and the marriage bed kept undefiled, for God will judge the sexually immoral and adulterers.
Context
2Ẹ má ṣe gbàgbé láti máa ṣe àlejò; nítorí pé nípa bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlòmíràn ṣe àwọn angẹli ní àlejò láìmọ̀. 3Ẹ máa rántí àwọn òǹdè bí ẹni tí a dè pẹ̀lú wọn, àti àwọn tí a ń pọn lójú bí ẹ̀yin tìkára yín pẹ̀lú tí ń bẹ nínú ara. 4Kí ìgbéyàwó lọ́lá láàrín gbogbo ènìyàn, kí àkéte si jẹ́ aláìléèérí, nítorí àwọn àgbèrè àti àwọn panṣágà ni Ọlọ́run yóò dá lẹ́jọ́. 5Kí ọkàn yín má ṣe fà sí ìfẹ́ owó, ki ohun tí ẹ ní tó yin; nítorí òun tìkára rẹ̀ ti wí pé,
“Èmi kò jẹ́ fi ọ́ sílẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni èmi kò jẹ́ kọ̀ ọ́ sílẹ̀.” 6Nítorí náà ni àwa ṣe ń fi ìgboyà wí pé,
“Olúwa ni olùrànlọ́wọ́ mi, èmi kì yóò bẹ̀rù;
kín ni ènìyàn lè ṣe sí mi?”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.