Habakuku 2:6
Habakkuk 2:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Gbogbo àwọn wọ̀nyí kì yóò máa pa òwe sí i tí wọn yóò sì máa kọ orin òwe sí i wí pé, “ ‘Ègbé ni fún ẹni tí ń mu ohun tí kì í ṣe tirẹ̀ pọ̀ sí i! Tí ó sì sọ ara rẹ̀ di ọlọ́rọ̀ nípasẹ̀ ìlọ́nilọ́wọ́gbà! Eléyìí yóò ha ti pẹ́ tó?’
Habakkuk 2:6 in English
Habakkuk 2:6 · Berean Standard Bible
Will not all of these take up a taunt against him, speaking with mockery and derision: ‘Woe to him who amasses what is not his and makes himself rich with many loans! How long will this go on?’
Context
4“Kíyèsi, ọkàn rẹ tí ó gbéga,
ìfẹ́ rẹ̀ kò dúró ṣinṣin nínú rẹ̀,
ṣùgbọ́n olódodo yóò wa nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀. 5Bẹ́ẹ̀ ni pẹ̀lú, nítorí tí ọtí wáìnì ni ẹ̀tàn,
agbéraga ènìyàn òun, kò sì ní sinmi
ẹni tí ó sọ ìwọra rẹ di gbígbòòrò bí isà òkú,
ó sì dàbí ikú, a kò sì le tẹ́ ẹ lọ́rùn,
ó kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ sí ọ̀dọ̀
ó sì gba gbogbo ènìyàn jọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. 6“Gbogbo àwọn wọ̀nyí kì yóò máa pa òwe sí i tí wọn yóò sì máa kọ orin òwe sí i wí pé,
“ ‘Ègbé ni fún ẹni tí ń mu ohun tí kì í ṣe tirẹ̀ pọ̀ sí i!
Tí ó sì sọ ara rẹ̀ di ọlọ́rọ̀ nípasẹ̀ ìlọ́nilọ́wọ́gbà!
Eléyìí yóò ha ti pẹ́ tó?’ 7Ǹjẹ́ ẹni ti ó yọ ọ́ lẹ́nu, kí yóò ha dìde ní òjijì?
Àti àwọn tí ó wàhálà rẹ kì yóò jí, kí wọn ó sì dẹ́rùbà ọ́?
Nígbà náà ni ìwọ yóò wa dí ìkógun fún wọn. 8Nítorí ìwọ ti kó Orílẹ̀-èdè púpọ̀,
àwọn ènìyàn tókù yóò sì kó ọ
nítorí ìwọ tí ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀; nítorí ẹ̀jẹ̀,
ìwọ tí pa ilẹ̀ àti ìlú ńlá run
àti gbogbo ènìyàn to ń gbé inú rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.