Habakuku 2:8
Habakkuk 2:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí ìwọ ti kó Orílẹ̀-èdè púpọ̀, àwọn ènìyàn tókù yóò sì kó ọ nítorí ìwọ tí ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀; nítorí ẹ̀jẹ̀, ìwọ tí pa ilẹ̀ àti ìlú ńlá run àti gbogbo ènìyàn to ń gbé inú rẹ̀.
Habakkuk 2:8 in English
Habakkuk 2:8 · Berean Standard Bible
Because you have plundered many nations, the remnant of the people will plunder you— because of your bloodshed against man and your violence against the land, the city, and all their dwellers.
Context
6“Gbogbo àwọn wọ̀nyí kì yóò máa pa òwe sí i tí wọn yóò sì máa kọ orin òwe sí i wí pé,
“ ‘Ègbé ni fún ẹni tí ń mu ohun tí kì í ṣe tirẹ̀ pọ̀ sí i!
Tí ó sì sọ ara rẹ̀ di ọlọ́rọ̀ nípasẹ̀ ìlọ́nilọ́wọ́gbà!
Eléyìí yóò ha ti pẹ́ tó?’ 7Ǹjẹ́ ẹni ti ó yọ ọ́ lẹ́nu, kí yóò ha dìde ní òjijì?
Àti àwọn tí ó wàhálà rẹ kì yóò jí, kí wọn ó sì dẹ́rùbà ọ́?
Nígbà náà ni ìwọ yóò wa dí ìkógun fún wọn. 8Nítorí ìwọ ti kó Orílẹ̀-èdè púpọ̀,
àwọn ènìyàn tókù yóò sì kó ọ
nítorí ìwọ tí ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀; nítorí ẹ̀jẹ̀,
ìwọ tí pa ilẹ̀ àti ìlú ńlá run
àti gbogbo ènìyàn to ń gbé inú rẹ̀. 9“Ègbé ni fún ẹni tí ń jẹ èrè ìjẹkújẹ sí ilé rẹ̀,
tí o sí gbé ìtẹ́ rẹ̀ lórí ibi gíga,
kí a ba le gbà á sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ibi! 10Ìwọ ti gbìmọ̀ ìtìjú sí ilé rẹ
nípa kíké ènìyàn púpọ̀ kúrò;
ìwọ sì ti pàdánù ẹ̀mí rẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.