Native Bible

Habakkuk 2:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Ègbé ni fún ẹni tí ń jẹ èrè ìjẹkújẹ sí ilé rẹ̀, tí o sí gbé ìtẹ́ rẹ̀ lórí ibi gíga, kí a ba le gbà á sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ibi!

Habakkuk 2:9 in English

Habakkuk 2:9 · Berean Standard Bible

Woe to him who builds his house by unjust gain, to place his nest on high and escape the hand of disaster!

Context

7Ǹjẹ́ ẹni ti ó yọ ọ́ lẹ́nu, kí yóò ha dìde ní òjijì? Àti àwọn tí ó wàhálà rẹ kì yóò jí, kí wọn ó sì dẹ́rùbà ọ́? Nígbà náà ni ìwọ yóò wa dí ìkógun fún wọn. 8Nítorí ìwọ ti kó Orílẹ̀-èdè púpọ̀, àwọn ènìyàn tókù yóò sì kó ọ nítorí ìwọ tí ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀; nítorí ẹ̀jẹ̀, ìwọ tí pa ilẹ̀ àti ìlú ńlá run àti gbogbo ènìyàn to ń gbé inú rẹ̀. 9“Ègbé ni fún ẹni tí ń jẹ èrè ìjẹkújẹ sí ilé rẹ̀, tí o sí gbé ìtẹ́ rẹ̀ lórí ibi gíga, kí a ba le gbà á sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ibi! 10Ìwọ ti gbìmọ̀ ìtìjú sí ilé rẹ nípa kíké ènìyàn púpọ̀ kúrò; ìwọ sì ti pàdánù ẹ̀mí rẹ. 11Nítorí tí òkúta yóò kígbe jáde láti inú ògiri wá, àti ìtí igi láti inú igi rírẹ́ wá yóò sì dá a lóhùn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.