Habakuku 1:14
Habakkuk 1:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìwọ sì tí sọ ènìyàn di bí ẹja inú Òkun, bí ohun tí ń rákò tí wọn ko ni alákòóso.
Habakkuk 1:14 in English
Habakkuk 1:14 · Berean Standard Bible
You have made men like the fish of the sea, like creeping things that have no ruler.
Context
12Olúwa, ǹjẹ́ láti ayérayé kọ ni ìwọ tí wà?
Olúwa Ọlọ́run mi. Ẹni mímọ́ mi, àwa kì yóò kú
Olúwa, ìwọ tí yàn wọn fún ìdájọ́;
Ọlọ́run alágbára, ìwọ tí fi ẹsẹ̀ wọn múlẹ̀ fún ìbáwí. 13Ojú rẹ mọ́ tónítóní láti wo ibi;
ìwọ kò le gbà ìwà ìkà
nítorí kí ni ìwọ ṣe gba àwọn alárékérekè láààyè?
Nítorí kí ni ìwọ ṣe dákẹ́ nígbà tí ẹni búburú ń pa
ẹni tí i ṣe olódodo ju wọn lọ run? 14Ìwọ sì tí sọ ènìyàn di bí ẹja inú Òkun,
bí ohun tí ń rákò tí wọn ko ni alákòóso. 15Àwọn ènìyàn búburú fi àwọ̀n wọn gbé wọn sókè
ó sì kó wọn jọ nínú àwọ̀n ńlá rẹ̀;
nítorí náà, ó dunnú, ó sì yọ̀ pẹ̀lú. 16Nítorí náà, ó rú ẹbọ sí àwọ̀n rẹ̀,
ó sì ń sun tùràrí fún àwọ̀n ńlá rẹ̀
nítorí pẹ̀lú àwọ̀n rẹ̀ ni ó fi ń gbé ní ìgbádùn
tí ó sì ń gbádùn pẹ̀lú oúnjẹ tí ó bá wù ú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.