Native Bible

Habakkuk 1:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn ènìyàn búburú fi àwọ̀n wọn gbé wọn sókè ó sì kó wọn jọ nínú àwọ̀n ńlá rẹ̀; nítorí náà, ó dunnú, ó sì yọ̀ pẹ̀lú.

Habakkuk 1:15 in English

Habakkuk 1:15 · Berean Standard Bible

The foe pulls all of them up * with a hook; he catches them in his dragnet, and gathers them in his fishing net; so he rejoices gladly.

Context

13Ojú rẹ mọ́ tónítóní láti wo ibi; ìwọ kò le gbà ìwà ìkà nítorí kí ni ìwọ ṣe gba àwọn alárékérekè láààyè? Nítorí kí ni ìwọ ṣe dákẹ́ nígbà tí ẹni búburú ń pa ẹni tí i ṣe olódodo ju wọn lọ run? 14Ìwọ sì tí sọ ènìyàn di bí ẹja inú Òkun, bí ohun tí ń rákò tí wọn ko ni alákòóso. 15Àwọn ènìyàn búburú fi àwọ̀n wọn gbé wọn sókè ó sì kó wọn jọ nínú àwọ̀n ńlá rẹ̀; nítorí náà, ó dunnú, ó sì yọ̀ pẹ̀lú. 16Nítorí náà, ó rú ẹbọ sí àwọ̀n rẹ̀, ó sì ń sun tùràrí fún àwọ̀n ńlá rẹ̀ nítorí pẹ̀lú àwọ̀n rẹ̀ ni ó fi ń gbé ní ìgbádùn tí ó sì ń gbádùn pẹ̀lú oúnjẹ tí ó bá wù ú. 17Ǹjẹ́ wọn yóò ha máa pa àwọ̀n wọn mọ́ ní òfìfo bí, tí wọn yóò sì pa orílẹ̀-èdè run láìsí àánú?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.