Gẹnẹsisi 49:7
Genesis 49:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìfibú ni ìbínú wọn nítorí tí ó gbóná púpọ̀, àti fún ìrunú wọn nítorí tí ó kún fún ìkà! Èmi yóò tú wọn ká ní Jakọbu, èmi ó sì fọ́n wọn ká ní Israẹli.
Genesis 49:7 in English
Genesis 49:7 · Berean Standard Bible
Cursed be their anger, for it is strong, and their wrath, for it is cruel! I will disperse them in Jacob and scatter them in Israel.
Context
5“Simeoni àti Lefi jẹ́ arákùnrin—
idà wọn jẹ́ ohun èlò ogun alágbára. 6Kí ọkàn mi má ṣe ni àṣepọ̀ pẹ̀lú wọn,
kí n má sì ṣe dúró níbí ìpéjọpọ̀ wọn,
nítorí wọ́n ti pa àwọn ènìyàn ní ìbínú wọn,
wọ́n sì da àwọn màlúù lóró bí ó ti wù wọ́n. 7Ìfibú ni ìbínú wọn nítorí tí ó gbóná púpọ̀,
àti fún ìrunú wọn nítorí tí ó kún fún ìkà!
Èmi yóò tú wọn ká ní Jakọbu,
èmi ó sì fọ́n wọn ká ní Israẹli. 8“Juda, àwọn arákùnrin rẹ yóò yìn ọ,
ọwọ́ rẹ yóò wà ní ọrùn àwọn ọ̀tá rẹ,
àwọn ọmọkùnrin baba rẹ yóò foríbalẹ̀ fún ọ. 9Ọmọ kìnnìún ni ọ́, ìwọ Juda,
o darí láti igbó ọdẹ, ọmọ mi.
Bí i kìnnìún, o ba mọ́lẹ̀, o sì sùn sílẹ̀ bí i abo kìnnìún,
ta ni ó tó bẹ́ẹ̀, kí o lé e dìde?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.