Native Bible

Genesis 49:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kí ọkàn mi má ṣe ni àṣepọ̀ pẹ̀lú wọn, kí n má sì ṣe dúró níbí ìpéjọpọ̀ wọn, nítorí wọ́n ti pa àwọn ènìyàn ní ìbínú wọn, wọ́n sì da àwọn màlúù lóró bí ó ti wù wọ́n.

Genesis 49:6 in English

Genesis 49:6 · Berean Standard Bible

May I never enter their council; may I never join their assembly. For they kill men in their anger, and hamstring oxen on a whim.

Context

4Ẹni ríru bí omi Òkun, ìwọ kì yóò tayọ mọ́, nítorí pé ìwọ gun ibùsùn baba rẹ, lórí àkéte mi, ìwọ sì bà á jẹ́ (ìwọ bá ọ̀kan nínú àwọn aya baba rẹ lòpọ̀). 5“Simeoni àti Lefi jẹ́ arákùnrin— idà wọn jẹ́ ohun èlò ogun alágbára. 6Kí ọkàn mi má ṣe ni àṣepọ̀ pẹ̀lú wọn, kí n má sì ṣe dúró níbí ìpéjọpọ̀ wọn, nítorí wọ́n ti pa àwọn ènìyàn ní ìbínú wọn, wọ́n sì da àwọn màlúù lóró bí ó ti wù wọ́n. 7Ìfibú ni ìbínú wọn nítorí tí ó gbóná púpọ̀, àti fún ìrunú wọn nítorí tí ó kún fún ìkà! Èmi yóò tú wọn ká ní Jakọbu, èmi ó sì fọ́n wọn ká ní Israẹli. 8“Juda, àwọn arákùnrin rẹ yóò yìn ọ, ọwọ́ rẹ yóò wà ní ọrùn àwọn ọ̀tá rẹ, àwọn ọmọkùnrin baba rẹ yóò foríbalẹ̀ fún ọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.