Native Bible

Genesis 36:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Adah bí Elifasi fún Esau, Basemati sì bí Reueli,

Genesis 36:4 in English

Genesis 36:4 · Berean Standard Bible

And Adah bore Eliphaz to Esau, Basemath gave birth to Reuel,

Context

2Nínú àwọn ọmọbìnrin Kenaani ni Esau ti fẹ́ àwọn ìyàwó rẹ̀: Adah ọmọbìnrin Eloni ará Hiti àti Oholibama, ọmọbìnrin Ana, ọmọ ọmọ Sibeoni ará Hifi. 3Ó sì tún fẹ́ Basemati ọmọ Iṣmaeli arábìnrin Nebaioti. 4Adah bí Elifasi fún Esau, Basemati sì bí Reueli, 5Oholibama pẹ̀lú sì bí Jeuṣi, Jalamu, àti Kora. Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ tí Esau bí ní Kenaani. 6Esau sì mú àwọn aya rẹ̀, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ àti gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀, àwọn ohun ọ̀sìn rẹ̀ àti àwọn ẹran ọ̀sìn mìíràn àti gbogbo ohun ìní mìíràn tí ó ní, ni Kenaani, ó sì kó lọ sí ilẹ̀ mìíràn, jìnà sí ibi tí Jakọbu arákùnrin rẹ̀ wà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.