Gẹnẹsisi 33:7
Genesis 33:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Lẹ́yìn náà ni Lea àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú dé, wọ́n sì tún tẹríba. Ní ìkẹyìn ni Josẹfu àti Rakeli dé, wọ́n sì tún tẹríba pẹ̀lú.
Genesis 33:7 in English
Genesis 33:7 · Berean Standard Bible
Leah and her children also approached and bowed down, and then Joseph and Rachel approached and bowed down.
Context
5Nígbà tí Esau sì ṣe àkíyèsí àwọn ìyàwó àti ọmọ Jakọbu, ó béèrè lọ́wọ́ Jakọbu pé, “Ti ta ni àwọn wọ̀nyí?”
Jakọbu sì fèsì wí pé, “Èyí ni àwọn ọmọ tí Ọlọ́run nínú àánú rẹ̀ ti fi fún ìránṣẹ́ rẹ.” 6Nígbà náà ni àwọn ìránṣẹ́bìnrin àti àwọn ọmọ wọn súnmọ́ tòsí, wọ́n sì tẹríba. 7Lẹ́yìn náà ni Lea àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú dé, wọ́n sì tún tẹríba. Ní ìkẹyìn ni Josẹfu àti Rakeli dé, wọ́n sì tún tẹríba pẹ̀lú. 8Esau sì béèrè pé, “Kí ni èrò rẹ tí o fi to àwọn ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ tí mo pàdé wọ̀nyí?”
Jakọbu dáhùn pé, “Kí n ba le rí ojúrere rẹ ni olúwa mi.” 9Ṣùgbọ́n Esau wí pé, “Tèmi ti tó mi, pa èyí tí o ní mọ́ fún ara rẹ.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.