Gẹnẹsisi 33:9
Genesis 33:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n Esau wí pé, “Tèmi ti tó mi, pa èyí tí o ní mọ́ fún ara rẹ.”
Genesis 33:9 in English
Genesis 33:9 · Berean Standard Bible
“I already have plenty, my brother,” Esau replied. “Keep what belongs to you.”
Context
7Lẹ́yìn náà ni Lea àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú dé, wọ́n sì tún tẹríba. Ní ìkẹyìn ni Josẹfu àti Rakeli dé, wọ́n sì tún tẹríba pẹ̀lú. 8Esau sì béèrè pé, “Kí ni èrò rẹ tí o fi to àwọn ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ tí mo pàdé wọ̀nyí?”
Jakọbu dáhùn pé, “Kí n ba le rí ojúrere rẹ ni olúwa mi.” 9Ṣùgbọ́n Esau wí pé, “Tèmi ti tó mi, pa èyí tí o ní mọ́ fún ara rẹ.” 10Jakọbu bẹ̀ ẹ́ wí pé, “Rárá bẹ́ẹ̀ kọ́, bí ó bá ṣe pé, mo rí ojúrere rẹ, jọ̀wọ́ gba ọrẹ lọ́wọ́ mi. Bí mo ṣe rí ojú rẹ̀ yìí, ó dàbí wí pé mo rí ojú Ọlọ́run ni báyìí, tí inú rẹ̀ ti dùn sí mi. 11Jọ̀wọ́ gba àwọn ohun tí mo mú wá wọ̀nyí lọ́wọ́ mi. Nítorí Ọlọ́run ti fi oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ hàn sí mi, gbogbo ohun tí mo fẹ́ sì ni mo ní.” Nígbà tí Jakọbu sì rọ̀ ọ́ pé Esau gbọdọ̀ gbà wọ́n, Esau sì gbà á.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.