Gẹnẹsisi 26:33
Genesis 26:33 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó sì pe orúkọ kànga náà ní Ṣiba, * títí di òní olónìí, orúkọ ìlú náà ni Beerṣeba.
Genesis 26:33 in English
Genesis 26:33 · Berean Standard Bible
So he called it Shibah,* and to this day the name of the city is Beersheba.*
Context
31Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì wọn búra fún ara wọn. Isaaki sì rán wọn lọ, wọ́n sì lọ ní àlàáfíà. 32Ní ọjọ́ náà gan an ni àwọn ìránṣẹ́ Isaaki wá sọ fún un pé àwọn ti kan omi ní kànga kan tí àwọn gbẹ́. 33Ó sì pe orúkọ kànga náà ní Ṣiba, * títí di òní olónìí, orúkọ ìlú náà ni Beerṣeba. 34Nígbà tí Esau pé ọmọ ogójì ọdún ó fẹ́ ọmọbìnrin kan tí a ń pè ní Juditi, ọmọ Beeri, ará Hiti, ó sì tún fẹ́ Basemati, ọmọ Eloni ará Hiti. 35Fífẹ́ tí a fẹ́ àwọn obìnrin wọ̀nyí jẹ́ ìbànújẹ́ fún Isaaki àti Rebeka.
26.21 tí ó túmọ̀ sí kànga àtakò
26.33 tí ó túmọ̀ sí, kànga májẹ̀mú
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.