Gẹnẹsisi 24:22
Genesis 24:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Lẹ́yìn tí àwọn ìbákasẹ náà ti mu omi tán, ni ọkùnrin náà mú òrùka wúrà ààbọ̀ ìwọ̀n ṣékélì àti júfù méjì fún ọwọ́ rẹ̀, tí ìwọ̀n ṣékélì wúrà mẹ́wàá.
Genesis 24:22 in English
Genesis 24:22 · Berean Standard Bible
And after the camels had finished drinking, he took out a gold ring weighing a beka,* and two gold bracelets for her wrists weighing ten shekels.*
Context
20Ó sì yára da omi inú ìkòkò omi rẹ̀ sínú ìbùmu, ó sáré padà lọ sí ibi omi láti pọn sí i wá fún àwọn ìbákasẹ, títí tí ó fi pọn fún gbogbo wọn. 21Láìsọ ọ̀rọ̀ kan, ìránṣẹ́ yìí ń wo ọmọbìnrin náà fínní fínní láti mọ̀ bóyá Olúwa ti ṣe ìrìnàjò òun ní rere tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. 22Lẹ́yìn tí àwọn ìbákasẹ náà ti mu omi tán, ni ọkùnrin náà mú òrùka wúrà ààbọ̀ ìwọ̀n ṣékélì àti júfù méjì fún ọwọ́ rẹ̀, tí ìwọ̀n ṣékélì wúrà mẹ́wàá. 23Lẹ́yìn náà, ó béèrè pé, “Ọmọ ta ni ìwọ í ṣe? Jọ̀wọ́ wí fún mi, ǹjẹ́ ààyè wà ní ilé baba rẹ láti wọ̀ sí ní alẹ́ yìí?” 24Ó dáhùn pé, “Betueli ọmọ tí Milka bí fún Nahori ni baba mi.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.