Native Bible

Genesis 24:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì yára da omi inú ìkòkò omi rẹ̀ sínú ìbùmu, ó sáré padà lọ sí ibi omi láti pọn sí i wá fún àwọn ìbákasẹ, títí tí ó fi pọn fún gbogbo wọn.

Genesis 24:20 in English

Genesis 24:20 · Berean Standard Bible

And she quickly emptied her jar into the trough and ran back to the well to draw water, until she had drawn water for all his camels.

Context

18Òun náà dáhùn pé, “Mu, olúwa mi,” ó sì yára sọ ìkòkò omi náà ka ọwọ́ rẹ̀, ó sì fún un mu. 19Lẹ́yìn tí ó ti fún un ni omi mu tán, ó wí pé, “Èmi ó bu omi fún àwọn ìbákasẹ rẹ pẹ̀lú títí wọn yóò fi mu àmutẹ́rùn.” 20Ó sì yára da omi inú ìkòkò omi rẹ̀ sínú ìbùmu, ó sáré padà lọ sí ibi omi láti pọn sí i wá fún àwọn ìbákasẹ, títí tí ó fi pọn fún gbogbo wọn. 21Láìsọ ọ̀rọ̀ kan, ìránṣẹ́ yìí ń wo ọmọbìnrin náà fínní fínní láti mọ̀ bóyá Olúwa ti ṣe ìrìnàjò òun ní rere tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. 22Lẹ́yìn tí àwọn ìbákasẹ náà ti mu omi tán, ni ọkùnrin náà mú òrùka wúrà ààbọ̀ ìwọ̀n ṣékélì àti júfù méjì fún ọwọ́ rẹ̀, tí ìwọ̀n ṣékélì wúrà mẹ́wàá.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.