Gẹnẹsisi 24:19
Genesis 24:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Lẹ́yìn tí ó ti fún un ni omi mu tán, ó wí pé, “Èmi ó bu omi fún àwọn ìbákasẹ rẹ pẹ̀lú títí wọn yóò fi mu àmutẹ́rùn.”
Genesis 24:19 in English
Genesis 24:19 · Berean Standard Bible
After she had given him a drink, she said, “I will also draw water for your camels, until they have had enough to drink.”
Context
17Ìránṣẹ́ náà súré lọ pàdé rẹ̀, ó sì wí fun un pé, “Jọ̀wọ́ fún mi ni omi díẹ̀ nínú ìkòkò omi rẹ.” 18Òun náà dáhùn pé, “Mu, olúwa mi,” ó sì yára sọ ìkòkò omi náà ka ọwọ́ rẹ̀, ó sì fún un mu. 19Lẹ́yìn tí ó ti fún un ni omi mu tán, ó wí pé, “Èmi ó bu omi fún àwọn ìbákasẹ rẹ pẹ̀lú títí wọn yóò fi mu àmutẹ́rùn.” 20Ó sì yára da omi inú ìkòkò omi rẹ̀ sínú ìbùmu, ó sáré padà lọ sí ibi omi láti pọn sí i wá fún àwọn ìbákasẹ, títí tí ó fi pọn fún gbogbo wọn. 21Láìsọ ọ̀rọ̀ kan, ìránṣẹ́ yìí ń wo ọmọbìnrin náà fínní fínní láti mọ̀ bóyá Olúwa ti ṣe ìrìnàjò òun ní rere tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.