Esekiẹli 38:10
Ezekiel 38:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“ ‘Èyí ni Olúwa Olódùmarè wí: Ní ọjọ́ náà èrò kan yóò wá sọ́kàn rẹ, ìwọ yóò sì pète ìlànà búburú.
Ezekiel 38:10 in English
Ezekiel 38:10 · Berean Standard Bible
This is what the Lord GOD says: On that day, thoughts will arise in your mind, and you will devise an evil plan.
Context
8Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́, àwa yóò bẹ̀ ọ wò; ní ọdún ìkẹyìn ìwọ yóò dó ti ilẹ̀ tí a ti gbà padà lọ́wọ́ idà, tí àwọn ènìyàn wọn kórajọ pọ̀ láti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè sí àwọn òkè gíga ti Israẹli, tí ó ti di ahoro fún ìgbà pípẹ́. A ti mú wọn jáde láti ọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè, nísinsin yìí gbogbo wọn ń gbé ní àìléwu. 9Ìwọ àti ọ̀wọ́ ogun rẹ àti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè pẹ̀lú rẹ yóò gòkè, ẹ̀yin yóò tẹ̀síwájú bí ìjì; ìwọ yóò dàbí ìkùùkuu tí ó bo ilẹ̀ mọ́lẹ̀. 10“ ‘Èyí ni Olúwa Olódùmarè wí: Ní ọjọ́ náà èrò kan yóò wá sọ́kàn rẹ, ìwọ yóò sì pète ìlànà búburú. 11Ìwọ yóò wí pé, “Èmi yóò gbé ogun ti ilẹ̀ àwọn tí a kò fi odi yíká, Èmi yóò gbé ogun ti àwọn ènìyàn àlàáfíà tí a kò funra sí gbogbo wọn ń gbé ní àìsí odi, ní àìsí ẹnu-ọ̀nà òde àti àsígbè-irin. 12Èmi yóò mú ohun ọdẹ, èmi yóò sì kó ìkógun, èmi yóò sì yí ọwọ́ mi padà sí ibi ìwólulẹ̀ ti a ti tún kọ́, àwọn ènìyàn tí a kójọpọ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè, tí ó ní ọrọ̀ nínú ẹran ọ̀sìn àti ẹrú, tí ó ń gbé ní àárín gbùngbùn ilẹ̀ náà.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.