Esekiẹli 38:8
Ezekiel 38:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́, àwa yóò bẹ̀ ọ wò; ní ọdún ìkẹyìn ìwọ yóò dó ti ilẹ̀ tí a ti gbà padà lọ́wọ́ idà, tí àwọn ènìyàn wọn kórajọ pọ̀ láti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè sí àwọn òkè gíga ti Israẹli, tí ó ti di ahoro fún ìgbà pípẹ́. A ti mú wọn jáde láti ọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè, nísinsin yìí gbogbo wọn ń gbé ní àìléwu.
Ezekiel 38:8 in English
Ezekiel 38:8 · Berean Standard Bible
After a long time you will be summoned. In the latter years you will enter a land that has recovered from war, whose people were gathered from many nations to the mountains of Israel, which had long been desolate. They had been brought out from the nations, and all now dwell securely.
Context
6Gomeri náà pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, àti Beti-Togarma láti jìnnàjìnnà àríwá pẹ̀lú gbogbo àwọn ọ̀wọ́ ogun rẹ̀—ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú rẹ̀. 7“ ‘Múra sílẹ̀, múra tán, kí ìwọ àti gbogbo ìjọ náà péjọpọ̀ pẹ̀lú rẹ, kí o sì pàṣẹ fún wọn. 8Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́, àwa yóò bẹ̀ ọ wò; ní ọdún ìkẹyìn ìwọ yóò dó ti ilẹ̀ tí a ti gbà padà lọ́wọ́ idà, tí àwọn ènìyàn wọn kórajọ pọ̀ láti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè sí àwọn òkè gíga ti Israẹli, tí ó ti di ahoro fún ìgbà pípẹ́. A ti mú wọn jáde láti ọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè, nísinsin yìí gbogbo wọn ń gbé ní àìléwu. 9Ìwọ àti ọ̀wọ́ ogun rẹ àti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè pẹ̀lú rẹ yóò gòkè, ẹ̀yin yóò tẹ̀síwájú bí ìjì; ìwọ yóò dàbí ìkùùkuu tí ó bo ilẹ̀ mọ́lẹ̀. 10“ ‘Èyí ni Olúwa Olódùmarè wí: Ní ọjọ́ náà èrò kan yóò wá sọ́kàn rẹ, ìwọ yóò sì pète ìlànà búburú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.