Esekiẹli 38:11
Ezekiel 38:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìwọ yóò wí pé, “Èmi yóò gbé ogun ti ilẹ̀ àwọn tí a kò fi odi yíká, Èmi yóò gbé ogun ti àwọn ènìyàn àlàáfíà tí a kò funra sí gbogbo wọn ń gbé ní àìsí odi, ní àìsí ẹnu-ọ̀nà òde àti àsígbè-irin.
Ezekiel 38:11 in English
Ezekiel 38:11 · Berean Standard Bible
You will say, ‘I will go up against a land of unwalled villages; I will come against a tranquil people who dwell securely, all of them living without walls or bars or gates—
Context
9Ìwọ àti ọ̀wọ́ ogun rẹ àti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè pẹ̀lú rẹ yóò gòkè, ẹ̀yin yóò tẹ̀síwájú bí ìjì; ìwọ yóò dàbí ìkùùkuu tí ó bo ilẹ̀ mọ́lẹ̀. 10“ ‘Èyí ni Olúwa Olódùmarè wí: Ní ọjọ́ náà èrò kan yóò wá sọ́kàn rẹ, ìwọ yóò sì pète ìlànà búburú. 11Ìwọ yóò wí pé, “Èmi yóò gbé ogun ti ilẹ̀ àwọn tí a kò fi odi yíká, Èmi yóò gbé ogun ti àwọn ènìyàn àlàáfíà tí a kò funra sí gbogbo wọn ń gbé ní àìsí odi, ní àìsí ẹnu-ọ̀nà òde àti àsígbè-irin. 12Èmi yóò mú ohun ọdẹ, èmi yóò sì kó ìkógun, èmi yóò sì yí ọwọ́ mi padà sí ibi ìwólulẹ̀ ti a ti tún kọ́, àwọn ènìyàn tí a kójọpọ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè, tí ó ní ọrọ̀ nínú ẹran ọ̀sìn àti ẹrú, tí ó ń gbé ní àárín gbùngbùn ilẹ̀ náà.” 13Ṣeba, Dedani àti àwọn oníṣòwò Tarṣiṣi àti gbogbo àwọn ọmọ kìnnìún wọn, yóò sọ fún un yín pé, “Ṣé ẹ̀yin wá fún ìkógun? Ṣé ẹ̀yin ti kó àwọn ogun yín jọ pọ̀ fún ìkógun, láti kó fàdákà àti wúrà lọ, láti kó ẹran ọ̀sìn àti ẹrú àti láti gba ọ̀pọ̀ ìkógun?” ’ ”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.