Esekiẹli 37:5
Ezekiel 37:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí fún àwọn egungun wọ̀nyí. Èmi yóò mú kí èémí wọ inú yín ẹ̀yin yóò sì wá di ààyè.
Ezekiel 37:5 in English
Ezekiel 37:5 · Berean Standard Bible
This is what the Lord GOD says to these bones: I will cause breath * to enter you, and you will come to life.
Context
3Olúwa sì bi mí léèrè, “Ọmọ ènìyàn, ǹjẹ́ àwọn egungun wọ̀nyí lè yípadà di àwọn ènìyàn bí?”
Èmi sì wí pé, “Ìwọ Olúwa Olódùmarè, ìwọ nìkan ni o lè dáhùn sí ìbéèrè yìí.” 4Nígbà náà ni ó wí fún mi pé, “Sọtẹ́lẹ̀ sí àwọn egungun kí ó sì sọ fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin egungun gbígbẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa! 5Èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí fún àwọn egungun wọ̀nyí. Èmi yóò mú kí èémí wọ inú yín ẹ̀yin yóò sì wá di ààyè. 6Èmi yóò so iṣan ara mọ́ ọn yín, Èmi yóò sì mú kí ẹran-ara wá sí ara yín, Èmi yóò sì fi awọ ara bò yín, Èmi yóò sì fi èémí sínú yín, ẹ̀yin yóò sì wà ní ààyè. Nígbà náà ẹ̀yin yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.’ ” 7Nítorí náà ni mo ṣe sọtẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti pa á láṣẹ fún mi. Bí mo sì ti ń sọtẹ́lẹ̀, ariwo wá, ìró tí ó kígbe sókè, àwọn egungun sì wà papọ̀, egungun sí egungun.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.