Esekiẹli 37:7
Ezekiel 37:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí náà ni mo ṣe sọtẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti pa á láṣẹ fún mi. Bí mo sì ti ń sọtẹ́lẹ̀, ariwo wá, ìró tí ó kígbe sókè, àwọn egungun sì wà papọ̀, egungun sí egungun.
Ezekiel 37:7 in English
Ezekiel 37:7 · Berean Standard Bible
So I prophesied as I had been commanded. And as I prophesied, there was suddenly a noise, a rattling, and the bones came together, bone to bone.
Context
5Èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí fún àwọn egungun wọ̀nyí. Èmi yóò mú kí èémí wọ inú yín ẹ̀yin yóò sì wá di ààyè. 6Èmi yóò so iṣan ara mọ́ ọn yín, Èmi yóò sì mú kí ẹran-ara wá sí ara yín, Èmi yóò sì fi awọ ara bò yín, Èmi yóò sì fi èémí sínú yín, ẹ̀yin yóò sì wà ní ààyè. Nígbà náà ẹ̀yin yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.’ ” 7Nítorí náà ni mo ṣe sọtẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti pa á láṣẹ fún mi. Bí mo sì ti ń sọtẹ́lẹ̀, ariwo wá, ìró tí ó kígbe sókè, àwọn egungun sì wà papọ̀, egungun sí egungun. 8Mo wò ó, iṣan ara àti ẹran-ara farahàn lára wọn, awọ ara sì bò wọ́n, ṣùgbọ́n kò sí èémí nínú wọn. 9Lẹ́yìn náà ni ó sọ fún mi pé, “Sọtẹ́lẹ̀ sí èémí; sọtẹ́lẹ̀, ọmọ ènìyàn, kí ó sì sọ fún un pé, ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: wá láti atẹ́gùn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, ìwọ èémí, kí ó sì mí èémí sínú àwọn tí a pa wọ̀nyí, kí wọn kí ó lè wà ní ààyè.’ ”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.