Native Bible

Ezekiel 37:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi yóò so iṣan ara mọ́ ọn yín, Èmi yóò sì mú kí ẹran-ara wá sí ara yín, Èmi yóò sì fi awọ ara bò yín, Èmi yóò sì fi èémí sínú yín, ẹ̀yin yóò sì wà ní ààyè. Nígbà náà ẹ̀yin yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.’ ”

Ezekiel 37:6 in English

Ezekiel 37:6 · Berean Standard Bible

I will attach tendons to you and make flesh grow upon you and cover you with skin. I will put breath within you so that you will come to life. Then you will know that I am the LORD.’”

Context

4Nígbà náà ni ó wí fún mi pé, “Sọtẹ́lẹ̀ sí àwọn egungun kí ó sì sọ fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin egungun gbígbẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa! 5Èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí fún àwọn egungun wọ̀nyí. Èmi yóò mú kí èémí wọ inú yín ẹ̀yin yóò sì wá di ààyè. 6Èmi yóò so iṣan ara mọ́ ọn yín, Èmi yóò sì mú kí ẹran-ara wá sí ara yín, Èmi yóò sì fi awọ ara bò yín, Èmi yóò sì fi èémí sínú yín, ẹ̀yin yóò sì wà ní ààyè. Nígbà náà ẹ̀yin yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.’ ” 7Nítorí náà ni mo ṣe sọtẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti pa á láṣẹ fún mi. Bí mo sì ti ń sọtẹ́lẹ̀, ariwo wá, ìró tí ó kígbe sókè, àwọn egungun sì wà papọ̀, egungun sí egungun. 8Mo wò ó, iṣan ara àti ẹran-ara farahàn lára wọn, awọ ara sì bò wọ́n, ṣùgbọ́n kò sí èémí nínú wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.