Native Bible

Ezekiel 36:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi yóò sọ iye ènìyàn àti ẹran dì púpọ̀ nínú yín, wọn yóò sì so èso, wọn yóò sì di púpọ̀ yanturu. Èmi yóò mú kí àwọn ènìyàn máa gbé nínú rẹ bí ti àtẹ̀yìnwá, èmi yóò sì mú kí o ṣe rere ju ìgbà àtijọ́ lọ. Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ pé èmi ni Olúwa.

Ezekiel 36:11 in English

Ezekiel 36:11 · Berean Standard Bible

I will fill you with people and animals, and they will multiply and be fruitful. I will make you as inhabited as you once were, and I will make you prosper more than before. Then you will know that I am the LORD.

Context

9Èmi ń ṣe àníyàn fún ọ, èmi yóò sì fi rere wọ̀ ọ́; àwa yóò tu ọ́, àwa yóò sì gbìn ọ́, 10èmi yóò sì sọ iye àwọn ènìyàn di púpọ̀ nínú rẹ àti gbogbo ilé Israẹli. Àwọn ìlú yóò di ibùgbé, a yóò sì tún àwọn ibi ìparun kọ́. 11Èmi yóò sọ iye ènìyàn àti ẹran dì púpọ̀ nínú yín, wọn yóò sì so èso, wọn yóò sì di púpọ̀ yanturu. Èmi yóò mú kí àwọn ènìyàn máa gbé nínú rẹ bí ti àtẹ̀yìnwá, èmi yóò sì mú kí o ṣe rere ju ìgbà àtijọ́ lọ. Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ pé èmi ni Olúwa. 12Èmi yóò mú kí àwọn ènìyàn, àní àwọn ènìyàn Israẹli, rìn lórí rẹ̀. Wọn yóò gbà ọ́, ìwọ yóò sì di ogún ìní wọn; ìwọ kì yóò sì gba àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ wọn mọ́. 13“ ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Nítorí pé àwọn ènìyàn sọ fún ọ pé, “Ìwọ pa àwọn ènìyàn run, ìwọ sì gba àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè lọ́wọ́ wọn,”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.