Esekiẹli 36:9
Ezekiel 36:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi ń ṣe àníyàn fún ọ, èmi yóò sì fi rere wọ̀ ọ́; àwa yóò tu ọ́, àwa yóò sì gbìn ọ́,
Ezekiel 36:9 in English
Ezekiel 36:9 · Berean Standard Bible
For behold, I am on your side; I will turn toward you, and you will be tilled and sown.
Context
7Nítorí náà, èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Èmi ṣe ìbúra nípa nína ọwọ́ mi sókè pé; àwọn orílẹ̀-èdè àyíká rẹ náà yóò jìyà ìfiṣẹ̀sín. 8“ ‘Ṣùgbọ́n ìwọ, òkè gíga Israẹli, yóò mú ẹ̀ka àti èso fún àwọn ènìyàn mi Israẹli, nítorí wọn yóò wá sílé ní àìpẹ́ yìí. 9Èmi ń ṣe àníyàn fún ọ, èmi yóò sì fi rere wọ̀ ọ́; àwa yóò tu ọ́, àwa yóò sì gbìn ọ́, 10èmi yóò sì sọ iye àwọn ènìyàn di púpọ̀ nínú rẹ àti gbogbo ilé Israẹli. Àwọn ìlú yóò di ibùgbé, a yóò sì tún àwọn ibi ìparun kọ́. 11Èmi yóò sọ iye ènìyàn àti ẹran dì púpọ̀ nínú yín, wọn yóò sì so èso, wọn yóò sì di púpọ̀ yanturu. Èmi yóò mú kí àwọn ènìyàn máa gbé nínú rẹ bí ti àtẹ̀yìnwá, èmi yóò sì mú kí o ṣe rere ju ìgbà àtijọ́ lọ. Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ pé èmi ni Olúwa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.