Esekiẹli 36:7
Ezekiel 36:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí náà, èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Èmi ṣe ìbúra nípa nína ọwọ́ mi sókè pé; àwọn orílẹ̀-èdè àyíká rẹ náà yóò jìyà ìfiṣẹ̀sín.
Ezekiel 36:7 in English
Ezekiel 36:7 · Berean Standard Bible
Therefore this is what the Lord GOD says: I have sworn with an uplifted hand that surely the nations around you will endure reproach of their own.
Context
5èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Ní ìgbóná ọkàn ní mo sọ̀rọ̀ sí àwọn kèfèrí yòókù, àti sí Edomu, nítorí pẹ̀lú ìbínú àti ìjowú ní ọkàn wọn ni wọ́n sọ ilé mi di ohun ìní wọn, kí wọn kí o lè kó pápá oko tútù rẹ̀.’ 6Nítorí náà, sọtẹ́lẹ̀ nípa ilẹ̀ Israẹli náà kí o sì sọ sí àwọn òkè gíga náà àti àwọn òkè kéékèèké, sí àwọn àfonífojì ńlá àti sí àwọn àfonífojì kéékèèké, ‘Èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Èmi sọ̀rọ̀ nínú ìrunú owú mi nítorí pé ìwọ ti jìyà ìfiṣẹ̀sín àwọn orílẹ̀-èdè. 7Nítorí náà, èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Èmi ṣe ìbúra nípa nína ọwọ́ mi sókè pé; àwọn orílẹ̀-èdè àyíká rẹ náà yóò jìyà ìfiṣẹ̀sín. 8“ ‘Ṣùgbọ́n ìwọ, òkè gíga Israẹli, yóò mú ẹ̀ka àti èso fún àwọn ènìyàn mi Israẹli, nítorí wọn yóò wá sílé ní àìpẹ́ yìí. 9Èmi ń ṣe àníyàn fún ọ, èmi yóò sì fi rere wọ̀ ọ́; àwa yóò tu ọ́, àwa yóò sì gbìn ọ́,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.