Native Bible

Ezekiel 36:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Ní ìgbóná ọkàn ní mo sọ̀rọ̀ sí àwọn kèfèrí yòókù, àti sí Edomu, nítorí pẹ̀lú ìbínú àti ìjowú ní ọkàn wọn ni wọ́n sọ ilé mi di ohun ìní wọn, kí wọn kí o lè kó pápá oko tútù rẹ̀.’

Ezekiel 36:5 in English

Ezekiel 36:5 · Berean Standard Bible

Therefore this is what the Lord GOD says: Surely in My burning zeal I have spoken against the rest of the nations, and against all Edom, who took My land as their own possession with wholehearted joy and utter contempt, so that its pastureland became plunder.

Context

3Nítorí náà, sọtẹ́lẹ̀ kí ó sì wí pé, ‘Èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Nítorí pé wọn sọ ọ di ahoro, tí wọn sì ń dọdẹ rẹ ní gbogbo ọ̀nà kí ìwọ kí ó lè di ìní fún àwọn orílẹ̀-èdè tí ó kù, àti ohun ti àwọn ènìyàn ń sọ ọ̀rọ̀ ìríra àti ìdíbàjẹ́ sí, 4nítorí náà, ẹ̀yin òkè gíga Israẹli gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa Olódùmarè, èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí fún àwọn òkè gíga àti àwọn òkè kéékèèké, fún àfonífojì ńlá àti àfonífojì kéékèèké, fún àwọn ibi ìsọdahoro ìparun àti fún àwọn ìlú tí a ti kọ̀sílẹ̀ tí a ti kó tí àwọn orílẹ̀-èdè tí ó kù ní àyíká sì fi ṣe ẹlẹ́yà, 5èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Ní ìgbóná ọkàn ní mo sọ̀rọ̀ sí àwọn kèfèrí yòókù, àti sí Edomu, nítorí pẹ̀lú ìbínú àti ìjowú ní ọkàn wọn ni wọ́n sọ ilé mi di ohun ìní wọn, kí wọn kí o lè kó pápá oko tútù rẹ̀.’ 6Nítorí náà, sọtẹ́lẹ̀ nípa ilẹ̀ Israẹli náà kí o sì sọ sí àwọn òkè gíga náà àti àwọn òkè kéékèèké, sí àwọn àfonífojì ńlá àti sí àwọn àfonífojì kéékèèké, ‘Èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Èmi sọ̀rọ̀ nínú ìrunú owú mi nítorí pé ìwọ ti jìyà ìfiṣẹ̀sín àwọn orílẹ̀-èdè. 7Nítorí náà, èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Èmi ṣe ìbúra nípa nína ọwọ́ mi sókè pé; àwọn orílẹ̀-èdè àyíká rẹ náà yóò jìyà ìfiṣẹ̀sín.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.