Native Bible

Ezekiel 36:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“ ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Nítorí pé àwọn ènìyàn sọ fún ọ pé, “Ìwọ pa àwọn ènìyàn run, ìwọ sì gba àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè lọ́wọ́ wọn,”

Ezekiel 36:13 in English

Ezekiel 36:13 · Berean Standard Bible

For this is what the Lord GOD says: Because people say to you, ‘You devour men and deprive your nation of its children,’

Context

11Èmi yóò sọ iye ènìyàn àti ẹran dì púpọ̀ nínú yín, wọn yóò sì so èso, wọn yóò sì di púpọ̀ yanturu. Èmi yóò mú kí àwọn ènìyàn máa gbé nínú rẹ bí ti àtẹ̀yìnwá, èmi yóò sì mú kí o ṣe rere ju ìgbà àtijọ́ lọ. Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ pé èmi ni Olúwa. 12Èmi yóò mú kí àwọn ènìyàn, àní àwọn ènìyàn Israẹli, rìn lórí rẹ̀. Wọn yóò gbà ọ́, ìwọ yóò sì di ogún ìní wọn; ìwọ kì yóò sì gba àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ wọn mọ́. 13“ ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Nítorí pé àwọn ènìyàn sọ fún ọ pé, “Ìwọ pa àwọn ènìyàn run, ìwọ sì gba àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè lọ́wọ́ wọn,” 14nítorí náà ìwọ kì yóò pa àwọn ènìyàn run tàbí mú kì orílẹ̀-èdè di aláìlọ́mọ mọ́, ni Olúwa Olódùmarè wí. 15Èmi kì yóò mú ki ó gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn láti ọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mọ́, ìwọ kì yóò jìyà ọ̀rọ̀ ìfiṣẹ̀sín láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tàbí mú kí orílẹ̀-èdè rẹ ṣubú, ni Olúwa Olódùmarè wí.’ ”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.