Esekiẹli 31:3
Ezekiel 31:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kíyèsi Asiria, tí ó jẹ́ igi kedari ni Lebanoni ní ìgbà kan rí, pẹ̀lú àwọn ẹ̀ka dáradára tí ó ṣẹ́ ìji bo igbó náà; tí ó ga sókè, òkè rẹ̀ lókè ni ewé tí ó nípọn wà.
Ezekiel 31:3 in English
Ezekiel 31:3 · Berean Standard Bible
Look at Assyria, a cedar in Lebanon, with beautiful branches that shaded the forest. It towered on high; its top was among the clouds.
Context
1Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù kẹta ọdún kọkànlá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá: 2“Ọmọ ènìyàn, sọ fún Farao ọba Ejibiti àti sí ìjọ rẹ̀:
“ ‘Ta ní a le fiwé ọ ní ọláńlá? 3Kíyèsi Asiria, tí ó jẹ́ igi kedari ni
Lebanoni ní ìgbà kan rí,
pẹ̀lú àwọn ẹ̀ka dáradára tí ó ṣẹ́ ìji bo igbó náà;
tí ó ga sókè,
òkè rẹ̀ lókè ni ewé tí ó nípọn wà. 4Omi mú un dàgbàsókè:
orísun omi tí ó jinlẹ̀ mú kí o dàgbàsókè;
àwọn odo rẹ̀ ń sàn yí ìdí rẹ̀ ká,
ó sì rán ìṣàn omi rẹ̀ sí gbogbo igi orí pápá. 5Nítorí náà ó ga sí òkè fíofío
ju gbogbo igi orí pápá lọ;
ẹ̀ka rẹ̀ pọ̀ sí i
àwọn ẹ̀ka rẹ̀ sì gùn,
wọn tẹ́ rẹrẹ nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.