Native Bible

Ezekiel 31:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí náà ó ga sí òkè fíofío ju gbogbo igi orí pápá lọ; ẹ̀ka rẹ̀ pọ̀ sí i àwọn ẹ̀ka rẹ̀ sì gùn, wọn tẹ́ rẹrẹ nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi.

Ezekiel 31:5 in English

Ezekiel 31:5 · Berean Standard Bible

Therefore it towered higher than all the trees of the field. Its branches multiplied, and its boughs grew long as it spread them out because of the abundant waters.

Context

3Kíyèsi Asiria, tí ó jẹ́ igi kedari ni Lebanoni ní ìgbà kan rí, pẹ̀lú àwọn ẹ̀ka dáradára tí ó ṣẹ́ ìji bo igbó náà; tí ó ga sókè, òkè rẹ̀ lókè ni ewé tí ó nípọn wà. 4Omi mú un dàgbàsókè: orísun omi tí ó jinlẹ̀ mú kí o dàgbàsókè; àwọn odo rẹ̀ ń sàn yí ìdí rẹ̀ ká, ó sì rán ìṣàn omi rẹ̀ sí gbogbo igi orí pápá. 5Nítorí náà ó ga sí òkè fíofío ju gbogbo igi orí pápá lọ; ẹ̀ka rẹ̀ pọ̀ sí i àwọn ẹ̀ka rẹ̀ sì gùn, wọn tẹ́ rẹrẹ nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi. 6Ẹyẹ ojú ọ̀run kọ ilé sí ẹ̀ka rẹ̀ gbogbo ẹranko igbó ń bímọ ní abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀; gbogbo orílẹ̀-èdè ńlá ń gbé abẹ́ ìji rẹ̀. 7Ọláńlá ní ẹwà rẹ̀ jẹ́, pẹ̀lú títẹ́ rẹrẹ ẹ̀ka rẹ̀, nítorí gbòǹgbò rẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀ sí ibi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi wà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.