Esekiẹli 27:7
Ezekiel 27:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọ̀gbọ̀ dáradára aṣọ iṣẹ́ ọnà abẹ́rẹ́ láti Ejibiti wá ni èyí tí ìwọ ta láti fi ṣe àsíá ọkọ̀ rẹ; aṣọ aláró àti elése àlùkò láti erékùṣù ti Eliṣa ni èyí tí a fi bò ó.
Ezekiel 27:7 in English
Ezekiel 27:7 · Berean Standard Bible
Of embroidered fine linen from Egypt they made your sail, which served as your banner. Of blue and purple from the coasts of Elishah they made your awning.
Context
5Wọn ṣe gbogbo pákó rẹ
ní igi junifa láti Seniri;
wọ́n ti mú igi kedari láti Lebanoni wá
láti fi ṣe òpó ọkọ̀ fún ọ. 6Nínú igi óákù ti Baṣani
ní wọn ti fi gbẹ́ ìtukọ̀ ọ̀pá rẹ̀;
ìjókòó rẹ ni wọn fi eyín erin ṣe pẹ̀lú
igi bokisi láti erékùṣù Kittimu wá. 7Ọ̀gbọ̀ dáradára aṣọ iṣẹ́ ọnà abẹ́rẹ́ láti Ejibiti wá
ni èyí tí ìwọ ta láti fi ṣe àsíá ọkọ̀ rẹ;
aṣọ aláró àti elése àlùkò
láti erékùṣù ti Eliṣa
ni èyí tí a fi bò ó. 8Àwọn ará ìlú Sidoni àti Arfadi ni àwọn atukọ̀ rẹ̀
àwọn ọlọ́gbọ́n ẹ̀rọ rẹ, ìwọ Tire,
ni àwọn atukọ̀ rẹ. 9Àwọn àgbàgbà Gebali,
àti àwọn ọlọ́gbọ́n ibẹ̀,
wà nínú ọkọ̀ bí òṣìṣẹ́ atukọ̀ rẹ,
gbogbo ọkọ̀ ojú Òkun
àti àwọn atukọ̀ Òkun
wá pẹ̀lú rẹ láti dòwò pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.