Native Bible

Ezekiel 27:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọn ṣe gbogbo pákó rẹ ní igi junifa láti Seniri; wọ́n ti mú igi kedari láti Lebanoni wá láti fi ṣe òpó ọkọ̀ fún ọ.

Ezekiel 27:5 in English

Ezekiel 27:5 · Berean Standard Bible

They constructed all your planking with cypress * from Senir.* They took a cedar from Lebanon to make a mast for you.

Context

3Sọ fún Tire, tí a tẹ̀dó sí ẹnu-bodè Òkun, oníṣòwò àwọn orílẹ̀-èdè fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ erékùṣù. ‘Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: “ ‘Ìwọ Tire wí pé, “Ẹwà mi pé.” 4Ààlà rẹ wà ní àárín Òkun; àwọn ọ̀mọ̀lé rẹ ti mú ẹwà rẹ pé. 5Wọn ṣe gbogbo pákó rẹ ní igi junifa láti Seniri; wọ́n ti mú igi kedari láti Lebanoni wá láti fi ṣe òpó ọkọ̀ fún ọ. 6Nínú igi óákù ti Baṣani ní wọn ti fi gbẹ́ ìtukọ̀ ọ̀pá rẹ̀; ìjókòó rẹ ni wọn fi eyín erin ṣe pẹ̀lú igi bokisi láti erékùṣù Kittimu wá. 7Ọ̀gbọ̀ dáradára aṣọ iṣẹ́ ọnà abẹ́rẹ́ láti Ejibiti wá ni èyí tí ìwọ ta láti fi ṣe àsíá ọkọ̀ rẹ; aṣọ aláró àti elése àlùkò láti erékùṣù ti Eliṣa ni èyí tí a fi bò ó.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.