Esekiẹli 27:30
Ezekiel 27:30 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọn yóò jẹ́ kí a gbọ́ ohùn wọn lòdì sí ọ wọn yóò sì sọkún kíkorò lé ọ lórí wọn yóò ku eruku lé orí ara wọn wọn yóò sì yí ara wọn nínú eérú.
Ezekiel 27:30 in English
Ezekiel 27:30 · Berean Standard Bible
They will raise their voices for you and cry out bitterly. They will throw dust on their heads and roll in ashes.
Context
28Ilẹ̀ etí Òkun yóò mì
nítorí ìró igbe àwọn atukọ̀ rẹ. 29Gbogbo àwọn alájẹ̀,
àwọn atukọ̀ Òkun
àti àwọn atọ́kọ̀ ojú Òkun;
yóò sọ̀ kálẹ̀ kúrò nínú ọkọ̀ wọn,
wọn yóò dúró lórí ilẹ̀. 30Wọn yóò jẹ́ kí a gbọ́ ohùn wọn lòdì sí ọ
wọn yóò sì sọkún kíkorò lé ọ lórí
wọn yóò ku eruku lé orí ara wọn
wọn yóò sì yí ara wọn nínú eérú. 31Wọn yóò fá irun orí wọn nítorí rẹ
wọn yóò wọ aṣọ yíya
wọn yóò pohùnréré ẹkún pẹ̀lú
ìkorò ọkàn nítorí rẹ
pẹ̀lú ohùn réré ẹkún kíkorò. 32Àti nínú arò wọn ni wọn yóò sì pohùnréré ẹkún fún ọ
wọn yóò sì pohùnréré ẹkún sórí rẹ, wí pé:
“Ta ni ó dàbí Tire
èyí tí ó parun ní àárín Òkun?”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.