Esekiẹli 27:28
Ezekiel 27:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ilẹ̀ etí Òkun yóò mì nítorí ìró igbe àwọn atukọ̀ rẹ.
Ezekiel 27:28 in English
Ezekiel 27:28 · Berean Standard Bible
The countryside will shake when your sailors cry out.
Context
26Àwọn atukọ̀ rẹ ti mú ọ
wá sínú omi ńlá.
Ṣùgbọ́n afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn yóò fọ́ ọ sí wẹ́wẹ́
ní àárín gbùngbùn Òkun. 27Ọrọ̀ rẹ, ọjà rẹ àti àwọn ohun títà rẹ,
àwọn ìṣúra rẹ, òṣìṣẹ́ ìtukọ̀ rẹ.
Àwọn oníbàárà rẹ àti gbogbo àwọn jagunjagun rẹ, tí ó wà nínú rẹ,
àti nínú gbogbo ẹgbẹ́ rẹ
tí ó wà ní àárín rẹ
yóò rì sínú àárín gbùngbùn Òkun
ní ọjọ́ ìparun rẹ. 28Ilẹ̀ etí Òkun yóò mì
nítorí ìró igbe àwọn atukọ̀ rẹ. 29Gbogbo àwọn alájẹ̀,
àwọn atukọ̀ Òkun
àti àwọn atọ́kọ̀ ojú Òkun;
yóò sọ̀ kálẹ̀ kúrò nínú ọkọ̀ wọn,
wọn yóò dúró lórí ilẹ̀. 30Wọn yóò jẹ́ kí a gbọ́ ohùn wọn lòdì sí ọ
wọn yóò sì sọkún kíkorò lé ọ lórí
wọn yóò ku eruku lé orí ara wọn
wọn yóò sì yí ara wọn nínú eérú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.