Esekiẹli 27:20
Ezekiel 27:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“ ‘Dedani ni oníṣòwò rẹ ní aṣọ ìjókòó-lẹ́sin fún ẹṣin-gígùn.
Ezekiel 27:20 in English
Ezekiel 27:20 · Berean Standard Bible
Dedan was your merchant in saddlecloths for riding.
Context
18“ ‘Damasku ni oníṣòwò rẹ, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ọjà tí ó ṣe àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀; ní ti ọtí wáìnì tí Helboni, àti irun àgùntàn funfun láti Sahari, 19àti ìdẹ̀ ọtí wáìnì láti Isali, ohun wíwọ̀: irin dídán, kasia àti kálàmù ni àwọn ohun pàṣípàrọ̀ fún ọjà rẹ. 20“ ‘Dedani ni oníṣòwò rẹ ní aṣọ ìjókòó-lẹ́sin fún ẹṣin-gígùn. 21“ ‘Àwọn ará Arabia àti gbogbo àwọn ọmọ-aládé ìlú Kedari àwọn ni àwọn oníbàárà rẹ; ní ti ọ̀dọ́-àgùntàn, àgbò àti ewúrẹ́, nínú ìwọ̀nyí ni wọ́n ti jẹ́ oníbàárà rẹ. 22“ ‘Àwọn oníṣòwò ti Ṣeba àti Raama, àwọn ni oníṣòwò rẹ; wọ́n ta onírúurú tùràrí olóòórùn dídùn dáradára ní ọjà rẹ, àti àwọn òkúta iyebíye àti wúrà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.