Native Bible

Ezekiel 27:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“ ‘Àwọn oníṣòwò ti Ṣeba àti Raama, àwọn ni oníṣòwò rẹ; wọ́n ta onírúurú tùràrí olóòórùn dídùn dáradára ní ọjà rẹ, àti àwọn òkúta iyebíye àti wúrà.

Ezekiel 27:22 in English

Ezekiel 27:22 · Berean Standard Bible

The merchants of Sheba and Raamah traded with you; for your wares they exchanged gold, the finest of all spices, and precious stones.

Context

20“ ‘Dedani ni oníṣòwò rẹ ní aṣọ ìjókòó-lẹ́sin fún ẹṣin-gígùn. 21“ ‘Àwọn ará Arabia àti gbogbo àwọn ọmọ-aládé ìlú Kedari àwọn ni àwọn oníbàárà rẹ; ní ti ọ̀dọ́-àgùntàn, àgbò àti ewúrẹ́, nínú ìwọ̀nyí ni wọ́n ti jẹ́ oníbàárà rẹ. 22“ ‘Àwọn oníṣòwò ti Ṣeba àti Raama, àwọn ni oníṣòwò rẹ; wọ́n ta onírúurú tùràrí olóòórùn dídùn dáradára ní ọjà rẹ, àti àwọn òkúta iyebíye àti wúrà. 23“ ‘Harani àti Kanneh àti Edeni, àwọn oníṣòwò Ṣeba, Asiria àti Kilmadi, ni àwọn oníṣòwò rẹ. 24Wọ̀nyí ní oníbàárà rẹ ní onírúurú nǹkan: aṣọ aláró, àti oníṣẹ́-ọnà àti àpótí aṣọ olówó iyebíye, tí a fi okùn dì, tí a sì fi igi kedari ṣe, nínú àwọn ilé-ìtajà rẹ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.