Esekiẹli 27:13
Ezekiel 27:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“ ‘Àwọn ará Giriki, Tubali, Jafani àti Meṣeki, ṣòwò pẹ̀lú rẹ, wọ́n fi ẹrù àti ohun èlò idẹ ṣe pàṣípàrọ̀ fún ọrọ̀ rẹ.
Ezekiel 27:13 in English
Ezekiel 27:13 · Berean Standard Bible
Javan,* Tubal, and Meshech were your merchants. They exchanged slaves and bronze utensils for your merchandise.
Context
11Àwọn ènìyàn Arfadi àti Heleki
wà lórí odi rẹ yíká;
àti àwọn akọni Gamadi,
wà nínú ilé ìṣọ́ rẹ.
Wọ́n fi àwọn asà wọn kọ ara odi rẹ;
wọn ti mú ẹwà rẹ pé. 12“ ‘Tarṣiṣi ṣòwò pẹ̀lú rẹ torí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ tí ó ní; wọn ṣe ìpààrọ̀ fàdákà, irin idẹ àti òjé fún ọjà títà rẹ̀. 13“ ‘Àwọn ará Giriki, Tubali, Jafani àti Meṣeki, ṣòwò pẹ̀lú rẹ, wọ́n fi ẹrù àti ohun èlò idẹ ṣe pàṣípàrọ̀ fún ọrọ̀ rẹ. 14“ ‘Àwọn ti ilé Beti-Togarma ṣe ìpààrọ̀ ẹṣin-ìṣiṣẹ́, ẹṣin ogun àti ìbáaka ṣòwò ní ọjà rẹ. 15“ ‘Àwọn ènìyàn Dedani ni àwọn oníṣòwò rẹ, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ erékùṣù ni wọ́n jẹ́ oníbàárà rẹ̀; wọ́n mú eyín erin àti igi eboni san owó rẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.