Native Bible

Ezekiel 27:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“ ‘Tarṣiṣi ṣòwò pẹ̀lú rẹ torí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ tí ó ní; wọn ṣe ìpààrọ̀ fàdákà, irin idẹ àti òjé fún ọjà títà rẹ̀.

Ezekiel 27:12 in English

Ezekiel 27:12 · Berean Standard Bible

Tarshish was your merchant because of your great wealth of goods; they exchanged silver, iron, tin, and lead for your wares.

Context

10“ ‘Àwọn ènìyàn Persia, Ludi àti Puti wà nínú jagunjagun rẹ àwọn ẹgbẹ́ ọmọ-ogun rẹ. Wọ́n gbé asà àti àṣíborí wọn ró sára ògiri rẹ, wọn fi ẹwà rẹ hàn. 11Àwọn ènìyàn Arfadi àti Heleki wà lórí odi rẹ yíká; àti àwọn akọni Gamadi, wà nínú ilé ìṣọ́ rẹ. Wọ́n fi àwọn asà wọn kọ ara odi rẹ; wọn ti mú ẹwà rẹ pé. 12“ ‘Tarṣiṣi ṣòwò pẹ̀lú rẹ torí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ tí ó ní; wọn ṣe ìpààrọ̀ fàdákà, irin idẹ àti òjé fún ọjà títà rẹ̀. 13“ ‘Àwọn ará Giriki, Tubali, Jafani àti Meṣeki, ṣòwò pẹ̀lú rẹ, wọ́n fi ẹrù àti ohun èlò idẹ ṣe pàṣípàrọ̀ fún ọrọ̀ rẹ. 14“ ‘Àwọn ti ilé Beti-Togarma ṣe ìpààrọ̀ ẹṣin-ìṣiṣẹ́, ẹṣin ogun àti ìbáaka ṣòwò ní ọjà rẹ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.