Esekiẹli 24:8
Ezekiel 24:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Láti bá à le jẹ́ kí ìbínú kí ó dé láti gbẹ̀san mo da ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí orí àpáta kan lásán, kí o ma bà á wà ni bíbò.
Ezekiel 24:8 in English
Ezekiel 24:8 · Berean Standard Bible
In order to stir up wrath and take vengeance, I have placed her blood on the bare rock, so that it would not be covered.’
Context
6Nítorí báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí:
“ ‘Ègbé ni fún ìlú ẹlẹ́jẹ̀ náà,
fún ìkòkò náà tí èérí rẹ̀ wà nínú rẹ̀,
tí èérí kò dà kúrò lójú rẹ̀!
Mú ẹran náà jáde ní ekìrí ekìrí
má ṣe ṣà wọ́n mú. 7“ ‘Nítorí ẹ̀jẹ̀ tí ó ta sílẹ̀ wà ní àárín rẹ̀;
à á sí orí àpáta kan lásán
kò dà á sí orí ilẹ̀,
níbi ti erùpẹ̀ yóò ti bò ó. 8Láti bá à le jẹ́ kí ìbínú kí ó dé láti gbẹ̀san
mo da ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí orí àpáta kan lásán,
kí o ma bà á wà ni bíbò. 9Nítorí náà báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí:
“ ‘Ègbé ni fún ìlú ẹlẹ́jẹ̀ náà!
Èmi pàápàá yóò jẹ́ kí òkìtì iná náà tóbi. 10Nítorí náà kó igi náà jọ sí i,
kí o sì fi iná sí i.
Ṣe ẹran náà dáradára,
fi tùràrí dùn ún;
kí o sì jẹ́ kí egungun náà jóná.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.