Native Bible

Ezekiel 24:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó ti ba gbogbo akitiyan jẹ: èérí rẹ̀ kò sì jáde kúrò lára rẹ̀, èérí náà gan an yóò wà nínú iná.

Ezekiel 24:12 in English

Ezekiel 24:12 · Berean Standard Bible

It has frustrated every effort; its thick rust has not been removed, even by the fire.

Context

10Nítorí náà kó igi náà jọ sí i, kí o sì fi iná sí i. Ṣe ẹran náà dáradára, fi tùràrí dùn ún; kí o sì jẹ́ kí egungun náà jóná. 11Lẹ́yìn náà gbé òfìfo ìkòkò náà lórí ẹyin iná kí idẹ rẹ̀ lè gbóná, kí ó lè pọ́n àti ki ìfófó rẹ̀ le di yíyọ́ nínú rẹ̀ kí èérí rẹ̀ le jó dànù. 12Ó ti ba gbogbo akitiyan jẹ: èérí rẹ̀ kò sì jáde kúrò lára rẹ̀, èérí náà gan an yóò wà nínú iná. 13“ ‘Nísinsin yìí èérí rẹ̀ ni ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wà. Nítorí mo gbìyànjú láti wẹ̀ ọ́ mọ́, ṣùgbọ́n ìwọ kò sì mọ́ kúrò nínú ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ, a kì yóò sì tún wẹ̀ ọ mọ́ kúrò nínú èérí rẹ, títí èmi yóò fi jẹ́ kí ìbínú mi balẹ̀ sórí rẹ̀. 14“ ‘Èmi Olúwa ni ó sọ ọ́, yóò sì ṣe, èmi yóò sì ṣe é. Èmi kì yóò padà sẹ́yìn; bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò dá sí i, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò yí ọkàn mi padà; gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ, àti gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ, ni wọn yóò dá ọ lẹ́jọ́, ni Olúwa Olódùmarè wí.’ ”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.