Esekiẹli 24:11
Ezekiel 24:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Lẹ́yìn náà gbé òfìfo ìkòkò náà lórí ẹyin iná kí idẹ rẹ̀ lè gbóná, kí ó lè pọ́n àti ki ìfófó rẹ̀ le di yíyọ́ nínú rẹ̀ kí èérí rẹ̀ le jó dànù.
Ezekiel 24:11 in English
Ezekiel 24:11 · Berean Standard Bible
Set the empty pot on its coals until it becomes hot and its copper glows. Then its impurity will melt within; its rust will be consumed.
Context
9Nítorí náà báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí:
“ ‘Ègbé ni fún ìlú ẹlẹ́jẹ̀ náà!
Èmi pàápàá yóò jẹ́ kí òkìtì iná náà tóbi. 10Nítorí náà kó igi náà jọ sí i,
kí o sì fi iná sí i.
Ṣe ẹran náà dáradára,
fi tùràrí dùn ún;
kí o sì jẹ́ kí egungun náà jóná. 11Lẹ́yìn náà gbé òfìfo ìkòkò náà lórí ẹyin iná
kí idẹ rẹ̀ lè gbóná, kí ó lè pọ́n
àti ki ìfófó rẹ̀ le di yíyọ́ nínú rẹ̀
kí èérí rẹ̀ le jó dànù. 12Ó ti ba gbogbo akitiyan jẹ:
èérí rẹ̀ kò sì jáde kúrò lára rẹ̀,
èérí náà gan an yóò wà nínú iná. 13“ ‘Nísinsin yìí èérí rẹ̀ ni ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wà. Nítorí mo gbìyànjú láti wẹ̀ ọ́ mọ́, ṣùgbọ́n ìwọ kò sì mọ́ kúrò nínú ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ, a kì yóò sì tún wẹ̀ ọ mọ́ kúrò nínú èérí rẹ, títí èmi yóò fi jẹ́ kí ìbínú mi balẹ̀ sórí rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.