Esekiẹli 23:32
Ezekiel 23:32 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Èyí yìí ní ohun ti Olúwa Olódùmarè wí: “Ìwọ yóò mu nínú ago ẹ̀gbọ́n rẹ, ago tí ó tóbi tí ó sì jinnú: yóò mú ìfiṣẹ̀sín àti ìfiṣe ẹlẹ́yà wá, nítorí tí ago náà gba nǹkan púpọ̀.
Ezekiel 23:32 in English
Ezekiel 23:32 · Berean Standard Bible
This is what the Lord GOD says: ‘You will drink your sister’s cup, a cup deep and wide. It will bring scorn and derision, for it holds so much.
Context
30Èmi yóò ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí sí ọ, nítorí ìwọ ti bá àwọn kèfèrí ṣe àgbèrè lọ, o sì fi àwọn òrìṣà wọn ba ara rẹ̀ jẹ́. 31Ìwọ ti rin ọ̀nà ti ẹ̀gbọ́n rẹ rìn, Èmi yóò sì fi ago rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́. 32“Èyí yìí ní ohun ti Olúwa Olódùmarè wí:
“Ìwọ yóò mu nínú ago ẹ̀gbọ́n rẹ,
ago tí ó tóbi tí ó sì jinnú:
yóò mú ìfiṣẹ̀sín àti ìfiṣe ẹlẹ́yà wá,
nítorí tí ago náà gba nǹkan púpọ̀. 33Ìwọ yóò mu àmupara àti ìbànújẹ́,
ago ìparun àti ìsọdahoro
ago ẹ̀gbọ́n rẹ Samaria. 34Ìwọ yóò mú un ni àmugbẹ;
ìwọ yóò sì fọ sí wẹ́wẹ́
ìwọ yóò sì fa ọmú rẹ̀ ya.
Èmi ti sọ̀rọ̀ ni Olúwa Olódùmarè wí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.