Esekiẹli 23:33
Ezekiel 23:33 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìwọ yóò mu àmupara àti ìbànújẹ́, ago ìparun àti ìsọdahoro ago ẹ̀gbọ́n rẹ Samaria.
Ezekiel 23:33 in English
Ezekiel 23:33 · Berean Standard Bible
You will be filled with drunkenness and grief, with a cup of devastation and desolation, the cup of your sister Samaria.
Context
31Ìwọ ti rin ọ̀nà ti ẹ̀gbọ́n rẹ rìn, Èmi yóò sì fi ago rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́. 32“Èyí yìí ní ohun ti Olúwa Olódùmarè wí:
“Ìwọ yóò mu nínú ago ẹ̀gbọ́n rẹ,
ago tí ó tóbi tí ó sì jinnú:
yóò mú ìfiṣẹ̀sín àti ìfiṣe ẹlẹ́yà wá,
nítorí tí ago náà gba nǹkan púpọ̀. 33Ìwọ yóò mu àmupara àti ìbànújẹ́,
ago ìparun àti ìsọdahoro
ago ẹ̀gbọ́n rẹ Samaria. 34Ìwọ yóò mú un ni àmugbẹ;
ìwọ yóò sì fọ sí wẹ́wẹ́
ìwọ yóò sì fa ọmú rẹ̀ ya.
Èmi ti sọ̀rọ̀ ni Olúwa Olódùmarè wí. 35“Nítorí náà báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Níwọ́n bí ìwọ ti gbàgbé mi, tí ìwọ sì ti fi mi sí ẹ̀yìn rẹ, ìwọ gbọdọ̀ gba àbájáde ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti panṣágà rẹ.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.