Esekiẹli 22:18
Ezekiel 22:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ọmọ ènìyàn, ilé Israẹli ti di ìdàrọ́ sí mi; gbogbo wọn jẹ́ bàbà, idẹ, irin àti òjé ti a fi sínú iná ìléru. Wọn jẹ́ ìdàrọ́ ti fàdákà.
Ezekiel 22:18 in English
Ezekiel 22:18 · Berean Standard Bible
“Son of man, the house of Israel has become dross to Me. All of them are copper, tin, iron, and lead inside the furnace; they are but the dross of silver.
Context
16Nígbà tí a ó bà ọ́ jẹ́ lójú àwọn orílẹ̀-èdè, ìwọ yóò mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa.’ ” 17Nígbà náà ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá: 18“Ọmọ ènìyàn, ilé Israẹli ti di ìdàrọ́ sí mi; gbogbo wọn jẹ́ bàbà, idẹ, irin àti òjé ti a fi sínú iná ìléru. Wọn jẹ́ ìdàrọ́ ti fàdákà. 19Nítorí náà èyí yìí ni ohun ti Olúwa Olódùmarè wí: ‘Nítorí tí ìwọ ti di ìdàrọ́, èmi yóò kó yín jọ sí Jerusalẹmu. 20Gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ṣe ń kó fàdákà, bàbà, irin, òjé àti idẹ jọ sínú iná ìléru láti fi iná yọ́ ọ, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò kó ọ jọ ní ìbínú àti ìrunú mi, èmi yóò sì fi ọ sì àárín ìlú, èmi yóò sì yọ́ ọ. Níbẹ̀ ní ìwọ yóò sì ti yọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.